Jeremiah 51:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà, wọ́n wà ní ibi ààbò wọn; àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin. Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná, àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn akọni Babeli ti dẹkun jijà, nwọn ti joko ninu ile-odi wọn; agbara wọn ti tán; nwọn di obinrin, nwọn tinabọ ibugbe rẹ̀; a ṣẹ́ ikere rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn jagunjagun Bábílónì tó dáwọ́ ìjà dúró la sí àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu ọ̀nà wọn ti di fífọ́.