Jeremiah 51:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn, bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan ti nsare yio sare lọ lati pade ẹnikeji ti nsare, ati onṣẹ kan lati pade onṣẹ miran, lati jiṣẹ fun ọba Babeli pe: a kó ilu rẹ̀ ni iha gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iránsẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún Ọba Bábílónì pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.