Jeremiah 51:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà. Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Bábílónì dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”