Jeremiah 51:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé, “Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò, n óo sì ba yín gbẹ̀san. N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ, n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi ni Oluwa wi; Wò o, emi o gba ijà rẹ jà, emi o si gba ẹsan rẹ, emi o si gbẹ okun rẹ̀, emi o si mu gbogbo orisun rẹ̀ gbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA wí: “Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san, èmi yóò mú kí omi òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.