Jeremiah 51:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ara wọn bá gbóná, n óo se àsè kan fún wọn. N óo rọ wọ́n lọ́tí yó, títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín, tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé. Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè, èmi yóò se àsè fún wọn, èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó débi tí wọn yóò máa kọ ẹ̀rín lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun àsùnjí,” ni OLÚWA wí.