Jeremiah 51:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni, Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé! Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí Sésákì yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé. Irú ìpàyà wo ni yóò bá Bábílónì láàrin àwọn orílẹ̀ èdè!