Jeremiah 51:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni, n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́, odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi ìyà jẹ Bélì ti Bábílónì àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì. Orílẹ̀ èdè kò ní i jẹ́ ìṣàn fún-un mọ́. Odi Bábílónì yóò sì wó.