Jeremiah 51:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù, nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà, nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí, tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀, tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ki ọkàn nyin má ba rẹ̀wẹsi, ati ki ẹ má ba bẹ̀ru, nitori iró ti a o gbọ́ ni ilẹ na; nitori iró na yio de li ọdun na, ati lẹhin na iró yio de li ọdun keji, ati ìwa-ika ni ilẹ na, alakoso yio dide si alakoso.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí a bá gbọ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa; àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí, òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.