Jeremiah 51:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni. Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa, yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, ti emi o bẹ awọn ere fifin Babeli wò: oju yio si tì gbogbo ilẹ rẹ̀, gbogbo awọn olupa rẹ̀ yio si ṣubu li ãrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Bábílónì, gbogbo ilẹ rẹ̀ ni a ó dójú tì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárin rẹ̀.