Jeremiah 51:48 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni, nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọrun ati aiye, ati gbogbo ohun ti o wà ninu wọn, yio si kọrin lori Babeli: nitori awọn afiniṣeijẹ yio wá sori rẹ̀ lati ariwa, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, yóò sì kọrin lórí Bábílónì: nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,” ni OLÚWA wí.