Jeremiah 51:52 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé, ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀; àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora, ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o ṣe ibẹwo lori awọn ere fifin rẹ̀: ati awọn ti o gbọgbẹ yio si mã gbin ja gbogbo ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí èmi yóò se ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fífin rẹ̀: àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa gbin já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀