Jeremiah 51:56 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí pé apanirun ti dé sí i, àní ó ti dé sí Babiloni. Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé, nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA, dájúdájú n óo gbẹ̀san.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe afiniṣeijẹ de sori rẹ̀, ani sori Babeli; a mu awọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nitori Ọlọrun ẹsan ni Oluwa, yio san a nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé afiniṣe ìjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Bábílónì; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni OLÚWA, yóò san án nítòótọ́.