Jeremiah 51:57 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó, pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọn yóo sun oorun àsùnrayè, wọn kò sì ní jí mọ́ laelae. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu ki awọn ijoye rẹ̀ yo bi ọ̀muti, ati awọn ọlọgbọn rẹ̀, awọn bàlẹ rẹ̀, ati awọn alakoso rẹ̀, ati awọn akọni rẹ̀, nwọn o si sun orun lailai, nwọn kì o si ji mọ́, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn alákòóṣo rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,” ní Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA ọmọ ogun.