Jeremiah 51:58 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀, a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío. Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe, àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni, nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: odi Babeli gbigboro li a o wó lulẹ patapata, ẹnu-bode giga rẹ̀ li a o si fi iná sun: tobẹ̃ ti awọn enia ti ṣiṣẹ lasan, ati awọn orilẹ-ède ti ṣiṣẹ fun iná, ti ãrẹ si mu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí: “Odi Bábílónì gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátapáta, ẹnu bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun: tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán, àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná, tí àárẹ̀ sì mú wọn.”