Jeremiah 51:64 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.” Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ si wipe, Bayi ni Babeli yio rì, kì o si tun dide kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori rẹ̀: ãrẹ̀ yio si mu wọn. Titi de ihin li ọ̀rọ Jeremiah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Bábílónì yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ” Títí dé ìhín nií ọ̀rọ̀ Jeremáyà.