Jeremiah 52:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣédékáyà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ Ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jọba ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọ Jeremáyà; láti Líbíná ló ti wá.