Jeremiah 52:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ogun awọn ara Kaldea, ti nwọn wà pẹlu balogun iṣọ, wó gbogbo odi Jerusalemu lulẹ yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ balógun ìṣọ́ wó gbogbo odi tí ó yí ìlú Jérúsálẹ́mù lulẹ̀.