Jeremiah 52:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó ninu awọn talaka awọn enia, ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu, ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ya lọ, ti o si ya tọ̀ ọba Babeli lọ, ati iyokù awọn ọ̀pọ enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nebusarádánì balógun ìsọ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú náà lọ sí ilẹ̀ àjèjì pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà tí ó kù àti gbogbo àwọn tí ó ti lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì.