Jeremiah 52:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ lẹba ile Oluwa, ati ijoko wọnni ati agbada idẹ nla ti o wà ni ile Oluwa ni awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó gbogbo idẹ wọn lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Bábílónì fọ́ idẹ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìjókòó tó ṣe é gbé kúrò àti àwọn ìdè wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní pẹpẹ OLÚWA. Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Bábílónì.