Jeremiah 52:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ìkoko wọnni, ati ọkọ́ wọnni, ati alumagaji fitila wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun elo idẹ wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ isin, ni nwọn kó lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò, ọkọ́ àti ọ̀pá fìtílà, àwọn ọpọ́n, síbí àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ.