Jeremiah 52:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Balógun àwọn ìṣẹ́ náà kó àwokòtò, ohun ìfọná, ọpọ́n ìkòkò, ọ̀pá fìtílà, síbí àti ago wáìnì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.