Jeremiah 52:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọwọ̀n meji, agbada nla kan, ati awọn malu idẹ mejila ti o wà labẹ ijoko, ti Solomoni ọba, ti ṣe fun ile Oluwa: idẹ gbogbo ohun-elo wọnyi alaini iwọ̀n ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọ̀wọ̀n méjì agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbèéká tí ó ṣe fún ibi pẹpẹ OLÚWA, èyí tí ó kọjá èyí tí a lè gbéléwọ̀n.