Jeremiah 52:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èṣo pomegiranátì ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èṣo pomegiranátì tí ó jọra.