Jeremiah 52:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pomegiranátì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranátì sì jẹ́ ọgọ́rùn ún kan.