Jeremiah 52:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú alásẹ tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn Ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.