Jeremiah 52:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹtàlélógún ènìyàn Júù tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjòjì jẹ́ márùn ún. Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.