Jeremiah 52:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, li ọdun kẹtadilogoji Jehoiakimu, ọba Juda, li oṣu kejila, li ọjọ kẹdọgbọn oṣu, Efil-Merodaki, ọba Babeli, li ọdun ekini ijọba rẹ̀, o gbe ori Jehoiakimu, ọba Juda, soke, o si mu u jade ninu ile túbu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹtàdín lógójì ti Jéhóáíkímù Ọba Júdà ni Efili-merodaki di Ọba Bábílónì. Ó tú Jéhóáíkímù Ọba Júdà sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kéjìlá.