Jeremiah 52:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó di ọdún kẹ́sàn án ti Sedekáyà tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹ́wàá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì sì lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.