Jeremiah 52:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrin odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà Ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Bábílónì yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ.