Jeremiah 6:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa, kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu, nítorí pé nǹkan burúkú ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ẸNYIN ọmọ Benjamini, ẹ ko ẹrù nyin salọ kuro li arin Jerusalemu, ẹ si fun fère ni Tekoa, ki ẹ si gbe àmi soke ni Bet-hakeremu, nitori ibi farahàn lati ariwa wá; ani iparun nlanla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ̀yin ènìyàn Bẹ́ńjámínì, sá síbi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jérúsálẹ́mù, Ẹ fọn fèrè ní Tékóà! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Bẹti-Ákérémù! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára.