Jeremiah 6:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́? Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà? Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́. Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn, wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ OLÚWA, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.