Jeremiah 6:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru, ara mi kò sì gbà á mọ́.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba, ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí. Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya, àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kún fún ìbínú OLÚWA, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kóra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.