Jeremiah 6:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilé wọn yóo di ilé onílé, oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni OLÚWA wí.