Jeremiah 6:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú há a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní ooru ìtìjú Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrin àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá fìyà jẹ” wọ́n ni OLÚWA wí.