Jeremiah 6:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré, ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́, níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́. Kí ẹ lè ní ìsinmi.” Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní, “A kò ní tọ ọ̀nà náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò, ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọ inú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rin nínú rẹ.’