Jeremiah 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ni anfaani turari, tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba, tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá? N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ère wo li o wà fun mi ninu turari lati Ṣeba wá, ati ẽsu daradara lati ilẹ ti o jina wá? ọrẹ sisun nyin kò ṣe inu-didun mi, ẹbọ jijẹ nyin kò wù mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti ṣébà wá, tàbí eso dáradára láti ilẹ̀ jínjìn réré? Ọrẹ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹbọ yín kò sì wù mí.”