Jeremiah 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi, wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ; ati baba, àtọmọ wọn, àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́, gbogbo wọn ni yóo parun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èyi ni ohun tí OLÚWA wí: “Èmi yóò gbé ohun ìdènà ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn bàbá àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”