Jeremiah 6:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀, ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú. Ìró wọn dàbí híhó omi òkun, bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀. Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun, wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú wọ́n ń hó bí omi òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹsin wọn lọ; wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”