Jeremiah 6:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú; ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo; kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé asọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín, kanṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.