Jeremiah 6:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò, o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò, o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn, kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.