Jeremiah 6:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn, wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn. Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin, àmúlùmálà ni gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀ òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.