Jeremiah 6:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga, bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu. Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀, àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi isun ti itú omi rẹ̀ jade, bẹ̃ni o ntú ìwa-buburu rẹ̀ jade: ìwa-ipa ati ìka li a gbọ́ niwaju mi nigbagbogbo ninu rẹ̀, ani aisan ati ọgbẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí kàǹga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún dún padà nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.