Jeremiah 6:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ, bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè. Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka, bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pesẹ́ ìyókù Ísírẹ́lì ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èṣo àjàrà jọ.”