Jeremiah 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.