Jeremiah 7:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí wọ́n bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn.