Jeremiah 7:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti a kì o pe e ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn a o pe e ni afonifoji ipakupa: nitori nwọn o sin oku ni Tofeti, titi àye kì yio si mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà kíyèsára ọjọ́-ń-bọ̀, ni OLÚWA wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Táfétì tàbí àfonífojì ti Beni Hínómì; àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tófẹ́tì títí kò fi ní sí àyè mọ́