Jeremiah 7:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu ki ohùn inu-didun ki o da kuro ni ilu Juda ati kuro ni ita Jerusalemu, ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ iyawo, ati ti iyawo; nitori ilẹ na yio di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọ tìyàwó ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

Recommended Reading