Jeremiah 7:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín.