Jeremiah 8:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI akoko na, li Oluwa wi, ni nwọn o hú egungun awọn ọba Juda ati egungun awọn ijoye, egungun awọn alufa ati egungun awọn woli, ati egungun awọn olugbe Jerusalemu kuro ninu isà wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ní ìgbà náà ni OLÚWA wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ijoye, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù kúrò nínú ibojì.