Jeremiah 8:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn, n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn. Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù, títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù. Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń já lẹ́nu; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.